E WOYE is a very interesting poem for us to digest on the concept of life, how it would have been if some concepts didn't exist in the world, the vacuum they will leave and how it will be very difficult to fill.
Ẹ WÒYE (BEHOLD)
Mo tún gbedé lọ́tun ọ̀tun
Oyinmọmọ adùn àrà ọ̀tọ̀ tún lèyí
Ó yàtọ̀ gédéńgbé si t'tẹ̀yìn wá
Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ wá bámi gbọ
Ẹ̀yin ọ̀mọ̀ràn ẹ wá bàmí wo
Ẹ jẹ́ a tún jo wòye si sàkun àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí
Ẹ jẹ á jọ wòye bóòni ayé ìbá ti ri
Ẹ jẹ á jọ rò ó bóòni àwùjọ ìbá ti ya
Ẹ jẹ á wo sàkùn ohun ìsẹ̀mí wa ìbá dà
Ẹ jẹ́ á wòye sáyé láìsí ìsẹ̀mí
Ọ̀run láìsí ìdájọ́
Ọjọ́ láìsí ìtímọ́
Alẹ́ láìsí ọ̀sán
Òòrùn láìsí òṣùpá
Ojú ọ̀run láìsí ìràwọ̀
Ilẹ̀ láìsí eèpẹ̀
Mọ́ṣálásí láìsí ìrun
Ṣọ́ọ̀ṣì láìsí ìsìn
Ìgbàlẹ̀ láìsí òsùbà
Níbo gan-an la à bá wà?
Taa la à bá máa sìn?
Ẹ jẹ́ á jọ ronú S'Ọ́jà láìsí èrò
Ìlú láìsí olórí
Ìletò láìsí Báálẹ̀
Àdúgbò láìsí mágàjí
Agbolé láìsí Báalé
Ọ̀dẹ̀dẹ̀ láìsí ọmọ ilé
Ọ̀tá láìsí ọ̀rẹ́
Bó o làwùjọ ìbá ti ri?
Kí la à bá fi yàtọ̀ si ẹranko?
Kí la à bá máa fí j'ọ́mọ ènìyàn?
Ẹ jẹ́ á wo sàkùn ebi láìsí oúńjẹ
Òùngbẹ láìsí omi
Àìsàn láìsí òògùn
Ìdùnu láìsí ẹ̀rín
Ìbànújẹ́ láìsí ẹkún
Òràn láìsí ìjìyà
Oore láìṣẹ́san
Ááwọ̀ láìsí ẹ̀tù
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ fún mi kíni a ò bá máa fi so ẹ̀mí ró?
Wọ́n ní Olú ló dáwa pẹ̀lú ẹwà àmọ́
Ẹ jẹ a wo orí láìsí etí
Ojú láì'ríran
Ọrùn láìsí iyùn
Eyín láìsí ètè
Imú láìsí gbọ́ òórùn
Ọwọ́ láìsí idẹ
Ẹsẹ láìsí ojúgun
Bèbèdí láìsí ìlẹ̀kẹ̀
Kí la à bá máa fi s'ẹ̀sọ́
Bó ó lọ́mọ ènìyàn ìbá rí
Ẹ ò si dákun jẹ́ á jọ wo sàkùn ìsẹ̀mí ayé wa
N gbọ́ kíni a o bà máa fi fọ ẹ̀mí mọ?
Ka kírun laini láda 😭😭😭
Ka gbàwẹ̀ láìsí asámú 😭😭😭
Ká kí Jimoh láìsí hútúbà 😭😭😭
S'ọdún láìsí yídì 😭😭😭
Wàásù láìsí ìpayà 😭😭😭
Anù láìsí ìràpadà 😭😭😭
Ká kú láìsíyè 😭😭😭
Kí laà bá fi fọ ẹ̀mí kúrò nínú ìdọ̀tí?
Ẹ jẹ á jọ wòye
✒✒✒©️
Mustapha Sherif
J.⭕.R.🅰
08147675392