Wednesday, June 9, 2021

Asa Iran Ara-Eni-Lowo Nile Yoruba

 ASA IRAN-ARA-ENI-LOWO NILE YORUBA

Yoruba karamasiki asa iran-ara-eni-lowo pupo nitori won gba pe ajeji owo kan ko gberu dori ati pe agbajo owo la fi n soya. Asa Iran Ara-Eni-Lowo je ona ti won nlo lati mu aye rorun fun ara won laye atijo, o tun je ona ti won n gba bo asiri ara won. O si je okan lara asa ile Yoruba to ti pe. Orisii ona ni won ngba se eyi, lara won ni:

1. AARO: awon to je egbe tabi igiripa lo ma n da aaro, ni opo igba won maa n je egbejegbe, won a ko ara won jo, won yoo si maa lo kaakiri lati bara sise lona ati mu ki ise naa ya. Ti won ba pari ise eni kan ni won yoo lo si ti elomiran. Dandan ki a san aaro pada

2. OWE: orisii owe lo wa nile yoruba, owe ti a se fun ana eni, ona ti a se fun eni airoju ba tabi idiwo ba ati owe ti a se fun ilu. Ninu owe a ma a n kora jo lati se iranlowo fun enikan laireti esan, a kii san owe pada sugbon ona ati ma je ki nnkan eni naa baje abi ona ati mu ki ise naa ya ni a fi maa n be owe

3. GBAMI-O-RAMI: eni ti aisan ba da gunle ni a maa se eyi fun. Babalawo tabi Onisegun yoo gbe iru eni bee sodo ti yoo si maa bo ati toju e titi yoo fi gbadun, ti ara re ba ya tan, dandan ni ki o fe Onisegun naa tabi Babalawo, bi o ba ko lati se bee, yoo san gbogbo owo ti eni naa na ati toju re tabi ki o pada sibi aare re.

4. EESU TABI ESUSU: awon ti won ba finu tan ara won ni won maa n da eesu, ti won ba da tan, won yo ko fun enikan titi yoo fi kari. Won yoo yan enikan bi eni ti yoo maa gba ajo naa, iru eni bayii kii gba owo kankan, o le je agbalagba tabi obinrin. Dandan ni ki a san aaro pada bi eeyan ba ko won a maa buni won ko si ni fokan tan iru onitohun mo layelaye

5. AJO: eyi yato si esusu, iye ti o ba da ni wa a ko ni ipari osu tabi ose, alajo yoo si yo owo tire nibe

6. ISINGABA TABI OKO OLOWO: igba ti a ba ya owo ti a koko tete rona ati san-an pada ni a ma n fi omo sodo olowo naa lati maa se iwofa nibe titi ta o fi rowo. O le je okunrin tabi obinrin sugbon ti o ba je obinrin baba olowo ko gbodo fun omo naa loyun bo ba sebe, omo naa yoo pada sile baba re, won yoo si pa gbese re, baba olowo naa ni lati dana fun eni to yawo ki o to le fe omo naa

6. SAN-AN DIEDIE: igba ti a ba fe raja ti owo wa ko to, a o ba eni to n taja soro ki o gba fun wa lati maa san owo iyoku diedie titi yoo fi tan. Nigba miran a le ma gbe oja naa kuro lodo e titi ta o fi san owo naa tan

7. FIFIDOGO: igba ti a ba fe ra nnkan ti owo wa ko ka ni a maa n se eyi, a o fi ohun kan lele fun eni ti a fe raja lodo re, ohun ti a gbodo fi lele gbodo ju ohun ti a fe ra lo

8. OWO EELE KIKO: ninu eyi a maa n fi ele si ori owo ti a ya nigba ti a ba fe san-an padan fun olowo. idaamu ni o saba maa n mu ni lo ya owo ele

Anfaaani Asa Iran Ara-Eni-Lowo 

1. O je ona ati mu aye rorun fun ara wa

2. O je ona ti a gba bo ara lasiri

3. O je ona ati mu ibasepo to damoran wa laarin eyin

4. O n je ki ife gbooro si

5. O je ona ati mu ise ya

6. A n fi n gbe Iran Yoruba laruge 

7. A maa n lo lati mo olooto eniyan nipa sisan gbese pada

8. O mu idagbasoke bá eeyan tabi awujo 

9. A fi n bu ola fun eeyan


Fun Ekun rere alaye, e wo fonran yii

©️Mustapha Sherif

J.🅾️.R.🅰️

No comments:

Asa Iran Ara-Eni-Lowo Nile Yoruba

 ASA IRAN-ARA-ENI-LOWO NILE YORUBA Yoruba karamasiki asa iran-ara-eni-lowo pupo nitori won gba pe ajeji owo kan ko gberu dori ati pe agbajo ...