Wednesday, June 24, 2020

Iwa Omoluabi

Omoluabi ni eni ti ebi, ore, ojulumo ka si ènìyàn gidi latari awon iwa re. Awon kan gbà pé omo ti Nua bí ni a n pe ni Omoluabi. Fun idi èyí gbogbo eni ti o ba kogi ja nínú iwa re si ebi, ara, ore ati aladugbo ni a n pe ni Omoluabi. 

Abuda Iwa Omoluabi
Iwa jẹ iṣesi eniyan kan laarin awọn olubagbe rẹ. Bi iṣesi ẹni ba dara, awọn eniyan yoo maa pe oluwarẹ ni oniwa rere. Bi iṣesi oluwarẹ ko ba si bojumu, awọn eniyan yoo maa pe e ni oniwa buburu. Awọn ti iwa wọn ba dara ni Yooba npe ni ọmọluwabi eniyan.
Ohun ti Yooba gba pe o jẹ iwa ọmọluwabi pọ pupọ.
1.O bẹrẹ lati ori kikini ti o fi de ori aajo eniyan ṣiṣe. Eyi ti a le sọ pe o jẹ ipilẹṣẹ iwa ọmọluwabi ni ikini. Yooba gba pe ẹni ti ko ba mọ eniyan ki ko yatọ si ilabiru baba ọbọ.
2. ibọwọ fun agba tun jẹ ọkan gbogi. Bi eniyan ba fi ọjọ kan ju ẹlomiran lọ, ọwọ(respect) ọjọ kan naa yoo wa lara rẹ titi dọjọ ogbo wọn ni. Bi Yooba ba si sọ pe papanlagi tabi ipanle ni ẹnikan, aini ibọwọ fun agba pẹlu ohun ti awọn n tọka si lara rẹ.
3. Ji jara Mose, omoluabi kìí fi ise jáfara, gbogbo ohun tóbá fe se asiko lo máa ń se e 
4. Ọmọluwabi gbọdọ jẹ ẹni ti o nfi ara balẹ gba imọran ti agba ba fun un. Bi o ba si ṣẹ(err), ti wọn ba tọka si ẹṣẹ rẹ, o gbọdọ le tuuba(ask for forgiveness).
Yooba ka ẹni ti ki i ba ṣe nnkan wọnyi si olori kunkun eniyan, iru ẹni bẹẹ ki i ṣe ọmọluwabi rara.
5. Ohun kan pataki ti Yooba tun fi n mọ ọmọluwabi ni iwa itiju. Yooba gba pe ẹnikẹni ti ko ba ni itiju, ki i ṣe ọmọluwabi ati pe ko si aarun ti ko si lara iru ẹni bẹẹ tan. Ẹni ti o ba ni itiju, ko ni jale, ko nii ṣeke, ko nii purọ, ko ni ja ajangbila, bẹẹ ni gbogbo iwa aibikita gbogbo iyoku ni ko ni i si lọwọ rẹ.
6. Riran ara ẹni lọwọ tun jẹ ọna kan ti a fi le mọ eniyan gẹgẹbi ọmọluwabi. Eyi ni pe ki a ma ni iwa anikan-jọpọn tabi iwa imọtara ẹni nikan(selfishness). Bi a ba ri ẹni ti o ku diẹ ki o to fun ti a si ṣe iranlọwọ fun iru eniyan bẹẹ, iwa ọmọluwabi ni a hu yẹn. Ọmọluwabi ko nii ba afọju lọna ko gba ọpa lọwọ rẹ; kaka bẹẹ, yoo baa di ọpa naa mu kọja de ibi ti ko ti nii ṣoro fun lati mọ ọna ni.


Ojuṣe gbogbo ọmọ Yooba ni lati jẹ ỌMỌLUWABI.

6 comments:

Jhola Exquisite accessories and collections said...

Oluko ede Yoruba, eku ise opolo.. This is a nice write up, keep it up.

Jhola Exquisite accessories and collections said...

Oluko ede Yoruba, eku ise opolo.. This is a nice write up, keep it up.

HABEEB EQUIPPED said...

Wow. Well researched and properly articulated. NEXT!

Unknown said...

Ẹ kú iṣẹ́ ọpọlọ, ọpọlọ náà kò ní jọ́bà làsẹ Èdùmàrè

Unknown said...

Nice write up dear. More knowledge and understanding from Above by His Grace

Unknown said...

I will learn how to digest Yoruba poem with you, keep it up dear bro

Asa Iran Ara-Eni-Lowo Nile Yoruba

 ASA IRAN-ARA-ENI-LOWO NILE YORUBA Yoruba karamasiki asa iran-ara-eni-lowo pupo nitori won gba pe ajeji owo kan ko gberu dori ati pe agbajo ...