ORÚKỌ ÀMÚNTỌ̀RUNWA
Pataki ni orúkọ sísọ àti jíjẹ jẹ́ nílẹ̀ Yorùbá, ìdí niyìí ti Yorùbá ṣe karamaski orúkọ tí wọn yoo sọ ọmọ won torí wọn gbà pé orúkọ ọmọ ní ìjánú ọmọ. Oríṣìíríṣìí orúkọ lówá nílẹ̀ bi orúkọ àbísọ, orúkọ ìdílé, oríkì, orúk ìnagije, orúkọ àmútọ̀runwá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n orúkọ àmútọ̀runwá yàtọ̀ gédégédé si ìyókù nítorí wọn kì í sábà fún ọmọ lórúko yìí àyàfi kó jẹ́ pe Ìṣẹ̀lẹ̀ kán ṣẹlẹ̀ yálà ká tó lóyún ọmọ náà, nínú oyún tàbí ìgbà ti wọn máa bí. Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sábà máa ñ jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì. Ìdí nìyìí tí wọn fí máa ba fún àwọn ọmọ wọ̀nyìí lórúko náà tórí Yorùbá gbà pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ tí mu orúkọ wá látọ̀run, orúkọ yìí naa ni wọ́n máa ñ tẹ̀ mọ ọmọ lára kódà bó bá jẹ́ pé wọn fún ní àwọn orúkọ miran.
Ohùn kan tó tún mú orúkọ àmútọ̀runwá yàtọ̀ nipé, àwọn orúkọ náà ni oríkì ti wọn lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí oríkì ìdílé wọn. Síwáju si ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ yìí ni wọ́n máa ñ ṣe ètùtù fún nígbà tan bá dáyé torí wọn gba pé àkàndá ni wọ́n.
Díẹ̀ nínú orúkọ àmúntọ̀runwa àti ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìṣẹ̀ṣe tó yí wọn ká ní ìwọ̀nyí:
1.Táyé: ni àkọ́kọ́ ọmọ nínú Ìbejì
2. Kẹ́hìndé: ni èkejì ọmọ nínú Ìbejì
3. Ẹ̀ta Òkò: ọmọ kẹta àwọn Ìbejì
4. Ìdòwú: ọmọ to a bi tèlé àwọn Ìbejì lobìnrin
5. Àlàbá: ọmọ tí a bi tèlé Ìdòwú
6. Ìdògbé: ọmọ tí abi tèlé Àlàbá
7. Ìdòhá: ọmọ tí a bí tèlé ìdògbé
8 Aina: ọmọbìnrin ti a bi tó gbe ibi kórùn wáyé
9. Ojo: ọmọkùnrin ti a bi tó gbe ibi kọ́rùn wáyé
10. Ìgè: ọmọ tó mú ẹsẹ̀ wáyé dípò orí
11. Ìlọ̀rí: ọmọ tí ìyá rẹ̀ kò ṣe nńkan oṣù tí a fi lóyún rẹ
12. Olúgbódi: ọmọ tó ní ìka ẹsẹ̀ mẹ́fà
13. Òní: ọmọ tó máa ń ké lọ́sàn-án àti lóru nígbà tí a bi
14. Ọ̀la: ọmọ tí a bí tèlé Òní
15. Abíára: ọmọ tí oyún rẹ ko ti i hàn tí bàbá rẹ̀ fi kú
16. Àjàyí: ọmọ tó dójú bolẹ̀ nígbà tí a bi
17. Tàlàbí: ni ọmọ tí a bi tó ekú bo orí àti ara rẹ
18: Ọ̀kẹ́: ọmọ tí a bi tówà nínú àpò
19: Dàda: ọmọ tí a bi tó irun orí rẹ̀ ta kókó
20. Èrinlé: ọmọ ti a bi ti o wé okùn ibi rẹ mọ́ ọwọ́ àbí ẹsẹ̀ wáyé
21. Igisanrín: ọmọ tí ìwọ́ inú rẹ̀ lọ́ wẹ́rẹ́kẹ́ wẹ́rẹ́kẹ́ bí okun ẹ̀ran
22. Amúsàn-án: ọmọkùnrin tí a bí pẹ̀lú isan eégún lọ́wọ́ rẹ̀
23. Ato: ọmọbìnrin ti a bi pẹ̀lú isan eégún lọ́wọ́ rẹ
24. Àṣà: ọmọ tí wọn bi tó su owó méjèèjì pọ.
25. Awẹ́: ọmọ tó kéré pupọ nígbà tí a bi
26. Ọmọpé: ọmọ tí oyún rẹ ju osù mẹ́sàn-án lọ kí wọn tó bi
27. Jọọ̀jọọ̀: ọmọ tí ìyá rẹ̀ kú bó ṣe bi i tan.
Fún ìbéèrè àti àlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́, ẹ pè sórí aago tàbí fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ lórí 08147675392
2 comments:
More wisdome
More wisdom and knowledge Sir
Post a Comment