Friday, April 9, 2021

ORISA SANGO

SANGO

Pipe ni a maa n pe Sango a kii ki i, Okunrin lo maa n gegun Sango, yoo dirun sori yoo si wo yeri ti won ran pelu aso pupa ti owo eyo wa lara re. Sango je eniyan lile, ti o n ba n soro ina a maa jade lenu re. Won gbagbo pe o loogun, o ni igboya, beeni o ni agbara lori ojo, ara ati imonamona

ITAN IGBESI  AYE SANGO

Bi o tile je pe orisii itan lo ro mo itan igbesi ayeSango ati eni ti Sango n se sugbon fun anfaani awon omo ile iwe sekondiri wa, Sango je Oba Alaafin Oyo ni aye atijo, Oun lagbo pe o daja sile laarin awon Ijoye meji ti okan fi pa ekeji eyi lo mu ki awon dite mo ti won si le jade nilu Oyo nigba naa. Sango ati awon iyawo re Oya, Osun ati Oba filu sile. Awon iranse re, Osumare ati Oru pada leyin re leyin igba ti won jade nilu, igba ti Sango ri pe oun ko ni eni leyin mo ni o ya si idi igi Ayan, to si poku so. Ibe ni a n pe ni Koso ni eba Oyo ti Iyawo re Oya wole si Ira o si dodo, Osun ati Oba naa dodo.

Awon ti won ri nibi ti o so si bere si se yeye  won si n yo suti ete si i pe Oba so! Oba so! inu Awon olutele Sango ko dun si eyi, idi ti won fi wa ogun buruku lo si ile Ibariba, won gba oogun buburu kan ti won fi n san ara pa awon ota Sango bi ojo ba ti n ro. Ti 'Edun Ara' ba ti paayan won a ni Sango lo n binu. idi niyi ti wonfi n pe Sango ni 'Jakuta'. Igba miiran, won le yo kelekele fina bole ni oru, won a ni Sango ni o n fi ibinu re han, igba ti wahala yii po ni awon ara Oyo yi ohun pada ti won beere si so pe "OBA KOSO", ki Sango le dawo iinu re duro. iberu yii si ni won fi so Sango di "Orisa Akunlebo".

AWON ORUKO MIIRAN TI SANGO N JE

1. Olúkòso: Ẹnití a mò mọ́ kòso tàbí oba tí ó wolè sí kòso.

2. Arèkújayé:

3. Àjàlájí:

4. Ayílègbe Òrun:

5. Olójú Orógbó: nítorípé orógbó ni obì tirè, òun ni ó sì máa ń ṣàféérí nígbà ayé rè. Orógbó náà sì ni a máa ń lo ní ojúbo sàngó títí di òní.

6. Èbìtì-àlàpà-peku-tiyètiyè: Òrìṣà tí ó máa ń fi ìbínú gbígbóná pa ènìyàn ni àpalàyà tàbí àpafòn.

7. Onibon òrun: gégé bí òrìsà ó ń mú kí àrá sán wá láti ojú òrun pèlú ìrókèkè tó lágbára.

8. Jàkúta: gégé bí òrìṣà tí ń fi òkúta jà (edùn àrá). Irúfẹ́ òkúta kékeré kan tí ó máa sekúpa ènìyàn nípasẹ̀ sàngó

9. Abotumo-bí-owú: Òrìsà léè wolé pa ènìyàn bi eni pé erù ń lá ni ó wólu irú eni bẹ́ẹ̀.

10. Èbìtì-káwó-pònyìn-soro: Irúfẹ́ Òrìṣà tí ó jẹ́ wí pé ìṣowó-sekúpa asebi rẹ̀ máa ńya ènìyàn lénu gidigidi.

11. Alágbára-inú-aféfé: Òrìsà tí ó jé wípé owọ́jà a re, máa ńwá láti inú aféfé tàbí òfurufú ni.

12. Abánjà-májẹ̀bi: òrìṣà tíí jà láì ṣègbè léyìn aṣebi tàbí ṣe àṣìmú elòmíràn fún oníṣé ibi.

13. Lánníkú-oko-oya: Òrìsà tí o ni èrù iku níkàwó

14. Òkokonkò èbìtì: Òrìsà tí ó le subú lu ènìyàn bii ìgànnán tí ó ti denukọlè

15. Eléèmò: Òrìsà tí ó ni èèmò

·      Awon Olusin Sango: Baba Mogba ni Olori awon oni Sango, Adosu Sango ati Elegun Sango (awon wonyii ni n runa)

·      Ami Sango: Ose, seere, laba, opon Sango, Odo Sango, (eyi ti awon gbenagbena ya ose, seere ati laba si), ati edun ara.

·      Ohun Irubo: Agbo, orogbo, akuko, amala pelu gbegiri gbigbona, obi, ataare ati eran obuko

·      Ilu Sango: Bata ni Sango n jo

·      Eewo: Awon adosu Sango ko gbodo je eran Esuo (Esuro), Eku Ago ati Ewa sese

ORIKI SANGO

 
Sango Olukoso
Akata yeri yeri
Arabambi Oko Oya
Oloju Orogbo
Elereke obi
Eleyinju ogunna
Olukoso lalu
E ègún tin'yona lenu
Orisa ti nbologbo leru
San'giri, la'giri
Ola'giri kankan figba edun bo
A ri igba ota, sete
O fi alapa segun ota
Ajisaye gbege oko oya
Oloju Orogbo, Sango olukorooo!...

 

No comments:

Asa Iran Ara-Eni-Lowo Nile Yoruba

 ASA IRAN-ARA-ENI-LOWO NILE YORUBA Yoruba karamasiki asa iran-ara-eni-lowo pupo nitori won gba pe ajeji owo kan ko gberu dori ati pe agbajo ...