Tuesday, November 3, 2020

ÌJÁLÁ ÀTI ÌRÈMỌ̀JÉ ARÉ ỌDẸ

ÌJÀLÁ: jẹ orísìí aré ọdẹ èyí tó máa ń wáyé nibi ayẹyẹ tàbí nígbá tí ọdẹ bá ń ṣọdẹ lọ nínú igbó. Kò sí ibi tí ọdẹ ò ti le sun Ìjálá yálà níbi ìkómọjáde, ìyàwó, ilé sísí, ìwúyè abbl. Yato fún eyi àwọn ode a maa sun Ìjálá nígbá tọ́wọ́ bá dilẹ̀ tí ń wọn gbafẹ yálà nidi ẹmu àbí ìdí ayò láti dárayá. Wọ́n a tún máa sún Ìjálá nígbá tí wọn bá ń ṣiṣẹ́ míràn bí, lágbẹ̀dẹ, lóko agbe, ìdí ọ̀pẹ, nibi iṣẹ́ ọna eyi láti mú kí iṣẹ́ yá. Lópó ìgbà làwọn ọdẹ máa ń sun Ìjálá nínú igbó láti má ké sí ara wọn kan ma bá a sọnù àbí nígbá tí wọn bá kó ẹran de ibi tí won fi ìpàdé si lati dúpẹ́ lọ́wọ́ Ogun pé ó jẹ́ kí ọwọ́ dẹ. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé Ògún lo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ni sún Ìjálá. Àpẹẹrẹ àwọn tó ń sun Ìjálá ni, Ogundare Foyanmu ni Ogbomoso, Àlàbí Ògúndìpẹ̀ ni Ṣakí, Akinkanjú Ọdẹ Ìlọrin (Ọmọ abiyakunmasi)

ÌRÈMỌ̀JÉ: naa jẹ orísìí aré ọdẹ èyí tí wọn máa ń sun nígbá tán nbá sìnkú ọdẹ, sípà ọdẹ tàbí ṣe àìsùn ọdẹ tó kú. Èyí yàtọ̀ gedengbe si Ìjálá bí ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn ọdẹ náà lóni méjèèjì sibẹ ibi òkú tàbí ọ̀fọ̀ ọdẹ nìkan ní a ti máa ń sun Ìrèmọ̀jé. Àwọn àgbà ọdẹ tàbí ọdẹ tó bá dántọ́ nìkan ló má ń sun Ìrèmọ̀jé láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún ọdẹ tó kú fún ìdí èyí, a lè pe Ìrèmọ̀jé ni ORIN ARÒ


PÀTÀKÌ ÌRÈMỌ̀JÉ FÚN ỌDẸ

1. O jẹ ẹyẹ ìkẹyìn fún ọdẹ tó kú èyí tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe fún

2. O jẹ ọ̀nà tí àwọn ọdẹ máa ń fi tú òkú tó kú lọ nípa sísí ÌPÀ ỌDẸ 

3. Nibi Ìrèmọ̀jé làwọn ọdẹ kékèké tí máa ń mọ nípa ọdẹ tó kú ati àwọn ise ribiribi tó tí ṣe

4. Ó jẹ ọ̀nà tí wọn ń fí kọ àwọn ọmọde ni Ìrèmọ̀jé sísun

5. Àwọn ọdẹ a máa fi àsírí han ara wọn lásìkò tí wọn bá ń sun Ìrèmọ̀jé nípa pipi Idán

6. Nibi Ìrèmọ̀jé ní àwọn ọdẹ tí máa ń bèèrè ìyọ̀nda lọ́wọ́ ọdẹ tó kú láti jogún rẹ

7. Nǹkan ìwúrí àti ẹyẹ ló jẹ fún ẹbí ọdẹ tó ku


ÌYÀTỌ̀ LÁÀRIN ÌJÁLÁ ÀTI ÌRÈMỌ̀JÉ 

1. Ìjálá jẹ orin ayọ, ìdùnu tó rọ̀ mọ́ ayẹyẹ ṣùgbọ́n Ìrèmọ̀jé jẹ orin arò tó rọ̀ mọ́ ìbánujẹ́

2. Kó sí ibi tí a kì í ti sun Ìjálá pàápàá jùlọ nibi ayẹyẹkáyẹyẹ ṣùgbọ́n nibi òkú ọdẹ tàbí ìpà ọdẹ nikan ní a ti ń sun Ìrèmọ̀jé

3. Kò sí ẹni tí kò lè sùn Ìjálá yálà ọmọdé tàbí àgbà ọdẹ ṣùgbọ́n àgbà ọdẹ nìkan ló máa ń sun Ìrèmọ̀jé.

4. A má ń sun Ìjálá lati tún pé àkíyèsí àwùjọ ṣùgbọ́n a kò lè lo Ìrèmọ̀jé

5. Alẹ́ nibi àìsùn ọdẹ ni a ti sábà máa ń sún Ìrèmọ̀jé ṣùgbọ́n Ìjálá máa ń wáyé nígbàkígbà

6. A máa n fi orin Ìjálá najú tàbí mú iṣẹ́ yá ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ̀ fún Ìrèmọ̀jé





©Mustapha Sherif

J.⭕.R.🅰️

08147675392

6 comments:

Unknown said...

👍👍👍

Eku ise opolo

THE TALKING PEN said...

I so much enjoyed this class.

Keep it up,the sky is actually telling your starting point.

Jhola Exquisite accessories and collections said...

Kare omo Yoruba rere. Olohun a tunbo GBA fun e, no gbadun eko yii pupo. Mura sii

Ademid said...

E Ku ise opolo

Unknown said...

Opo yín kòní jóbà

Unknown said...

Omo ologo
Was gbayi

Asa Iran Ara-Eni-Lowo Nile Yoruba

 ASA IRAN-ARA-ENI-LOWO NILE YORUBA Yoruba karamasiki asa iran-ara-eni-lowo pupo nitori won gba pe ajeji owo kan ko gberu dori ati pe agbajo ...